11. “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa?Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ?Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu.
12. O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì.
13. O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada,o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ.
14. Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì,jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini.