1. Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní:“N óo kọrin sí OLUWA,nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo.Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa.
2. OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi,n óo máa yìn ín.Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi;n óo máa gbé e ga.
3. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀.
4. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun,ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa.
5. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta.
6. Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA;OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.