1. Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní:“N óo kọrin sí OLUWA,nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo.Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa.
2. OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi,n óo máa yìn ín.Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi;n óo máa gbé e ga.
3. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀.
4. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun,ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa.
5. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta.
6. Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA;OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.
7. Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀,o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko.
8. Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ,ìkún omi dúró lóòró bí òkítì,ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun.
9. Ọ̀tá wí pé,‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n;n óo pín ìkógun,n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn.N óo fa idà mi yọ,ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’
10. Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá.
11. “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa?Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ?Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu.
12. O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì.