Efesu 5:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun.

6. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn.

7. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn.

8. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.

9. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́.

10. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa.

11. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí.

12. Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ.

Efesu 5