Efesu 5:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun.

2. Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.

3. Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.

4. Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín.

Efesu 5