1. “Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín.
2. Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́.