8. Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti.
9. Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran,
10. a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú.
11. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.
12. “Bi ẹ bá fetí sí òfin wọnyi, tí ẹ sì pa wọ́n mọ́, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú majẹmu tí ó bá àwọn baba yín dá ṣẹ lórí yín, yóo sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.