47. Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn
48. láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),
49. ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga.