Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.