Diutaronomi 32:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó ní:“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé.

2. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára.

3. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀.

Diutaronomi 32