19. “Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí o bá jáde.
20. “Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà.
21. OLUWA yóo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ọ títí tí yóo fi pa ọ́ run patapata, lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti gbà.
22. OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun.
23. Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.
24. Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata.
25. “OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.
26. Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò.
27. OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn.
28. OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́.