26. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa.
27. Nítorí pé, inú igbó ni ó ti kì í mọ́lẹ̀. Bí ọmọbinrin àfẹ́sọ́nà yìí tilẹ̀ ké: ‘Gbà mí! Gbà mí!’ Kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí ó lè gbà á sílẹ̀.
28. “Bí ọkunrin kan bá rí ọmọbinrin kan, tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó kì í mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n,