Diutaronomi 17:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli,

5. ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

6. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.

7. Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.

8. “Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn.

Diutaronomi 17