25. Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu.
26. Ìran ti ẹbọ àṣáálẹ́ ati ti òwúrọ̀ tí a ti là yé ọ yóo ṣẹ dájúdájú; ṣugbọn, pa àṣírí ìran yìí mọ́ nítorí ọjọ́ tí yóo ṣẹ ṣì jìnnà.”
27. Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi.