Daniẹli 4:25-33 BIBELI MIMỌ (BM)

25. A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́.

26. Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé.

27. Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”

28. Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára.

29. Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni,

30. ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”

31. Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ,

32. a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”

33. Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ.

Daniẹli 4