11. Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé.
12. Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.
13. “Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́,
14. ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀.
15. Ṣugbọn fi kùkùté, ati gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìdè irin ati ti idẹ ninu pápá.“ ‘Jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ koríko;
16. kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje.