Daniẹli 3:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba.

14. Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?

15. Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

16. Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí.

17. Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.

18. Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”

Daniẹli 3