40. “Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò.
41. Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.
42. Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
43. Yóo di aláṣẹ lórí wúrà, fadaka ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ilẹ̀ Ijipti; àwọn ará Libia ati Etiopia yóo máa tẹ̀lé e lẹ́yìn.