Pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ń bọ oriṣa àjèjì kan, yóo bá àwọn ìlú olódi tí wọ́n lágbára jùlọ jà. Yóo bu ọlá fún àwọn tí wọ́n bá yẹ́ ẹ sí. Yóo fi wọ́n jẹ olórí ọpọlọpọ eniyan; yóo sì fi ilẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tí wọ́n bá fún un lówó.