1. “Ní ọdún kinni ìjọba Dariusi ará Mede, mo dúró tì í láti mú un lọ́kàn le ati láti bá a fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.
2. Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.”Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun.
3. “Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú.