4. kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea.
5. Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.
6. Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda.
7. Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.
8. Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́.
9. Ọlọrun jẹ́ kí Daniẹli bá ojurere ati àánú olórí àwọn ìwẹ̀fà náà pàdé.
10. Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba.