Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.