17. Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.
18. Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa.
19. Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria.
20. Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà.
21. Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?”
22. Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.”