13. “Ẹ lọ bèèrè ohun tí a kọ sinu ìwé yìí lọ́wọ́ OLUWA fún èmi ati fún gbogbo eniyan Juda. OLUWA ń bínú sí wa gidigidi nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò ṣe ohun tí ìwé yìí pa láṣẹ fún wa.”
14. Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà.
15. Ó bá rán wọn pada, ó ní: “Ẹ lọ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé,
16. ‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà.