Àwọn Ọba Keji 2:18-22 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọ́n pada wá jábọ̀ fún Eliṣa ní Jẹriko, ó sì wí fún wọn pé, “Ṣebí mo ti sọ fun yín pé kí ẹ má lọ?”

19. Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20. Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí.

21. Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ sí ibi orísun omi náà, ó da iyọ̀ náà sí i, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA wí, ‘Mo sọ omi yìí di ọ̀tun lónìí, kò ní fa ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ba oyún jẹ́ mọ́.’ ”

22. Láti ìgbà náà ni omi náà ti dára títí di òní olónìí gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ.

Àwọn Ọba Keji 2