3. Joaṣi wà ní ìpamọ́ ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa, Atalaya sì ń jọba lórí ilẹ̀ Juda.
4. Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n.
5. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin.
6. (Ìdámẹ́ta yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà Suri; ìdámẹ́ta yòókù yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó wà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin), wọn yóo dáàbò bo ààfin.