Àwọn Ọba Keji 10:25-28 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ní kété tí Jehu parí rírú ẹbọ sísun rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ ati àwọn olórí ogun pé kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì pa gbogbo wọn; ẹnikẹ́ni kò si gbọdọ̀ jáde. Wọ́n bá wọlé, wọ́n fi idà pa gbogbo wọn, wọ́n sì wọ́ òkú wọn síta. Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ inú ibi mímọ́ Baali lọ,

26. wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná.

27. Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí.

28. Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli.

Àwọn Ọba Keji 10