10. Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
11. Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.”
12. Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
13. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí.