5. Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.”
6. Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.”
7. Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”
8. Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni.
9. Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀.