Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?”