7. Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti.
8. Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9. “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.
10. Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’