14. N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada,wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́,wọn yóo sì máa gbé inú wọn.Wọn yóo gbin àjàrà,wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀.Wọn yóo ṣe ọgbà,wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀.
15. N óo fẹsẹ̀ àwọn eniyan mi múlẹ̀lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,a kò sì ní ṣí wọn nípò pada mọ́lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn.Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”