8. Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.
9. Gbogbo ibi gíga Isaaki yóo di ahoro, ilé mímọ́ Israẹli yóo parun, n óo yọ idà sí ìdílé ọba Jeroboamu.”
10. Nígbà náà ni Amasaya, alufaa Bẹtẹli, ranṣẹ sí Jeroboamu, ọba Israẹli pé: “Amosi ń dìtẹ̀ mọ́ ọ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóo sì ba gbogbo ilẹ̀ yìí jẹ́.
11. Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ”
12. Amasaya sọ fún Amosi pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ aríran, pada lọ sí ilẹ̀ Juda, máa lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n sì máa fún ọ ní oúnjẹ.
13. Má sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Bẹtẹli mọ́, nítorí ibi mímọ́ ni, fún ọba ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
14. Amosi bá dáhùn, ó ní: “Èmi kì í ṣe wolii tabi ọmọ wolii, darandaran ni mí, èmi a sì tún máa tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́.
15. OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun.
16. Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nisinsinyii, ṣé o ní kí n má sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́, kí n má sì waasu fún àwọn ọmọ Isaaki mọ́?
17. Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLUWA sọ: ‘Iyawo rẹ yóo di aṣẹ́wó láàrin ìlú, àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin yóo kú sójú ogun, a óo pín ilẹ̀ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn; ìwọ pàápàá yóo sì kú sí ilẹ̀ àwọn alaigbagbọ; láìṣe àní àní, a óo kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn.’ ”