7. “Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.
8. “Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà?“OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?”
9. Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.
10. “Àwọn eniyan wọnyi ń kó nǹkan tí wọ́n fi ipá ati ìdigunjalè gbà sí ibi ààbò wọn, wọn kò mọ̀ bí à á tíí ṣe rere.”
11. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.”
12. OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.”