10. Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.”
11. OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn.
12. Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.”
13. OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn.
14. Nítorí náà, n óo sọ iná sí orí odi ìlú Raba, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. Ariwo yóo sọ ní ọjọ́ ogun, omi òkun yóo ru sókè ní ọjọ́ ìjì;
15. ọba wọn ati àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo sì lọ sí ìgbèkùn.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.