Aisaya 66:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ.Kí ìrora obí tó mú un,ó ti bí ọmọkunrin kan.

8. Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10. Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12. Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

13. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

14. Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,bí ìgbà tí koríko bá rúwé.Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

15. Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì,láti fi ìrúnú san ẹ̀san,yóo sì fi ahọ́n iná báni wí.

Aisaya 66