Aisaya 60:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo,a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.

12. Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun,wọn óo di àwópalẹ̀ patapata.

13. “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo.

14. Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.

Aisaya 60