Aisaya 57:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13. Nígbà tí o bá kígbe,kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọAfẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,ni yóo ni ilẹ̀ náà,òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.

14. OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15. Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.Láti sọ ọkàn wọn jí.

16. Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,Èmi ni mo dá èémí ìyè.

Aisaya 57