1. Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́?Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?
2. Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwéati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.Ìrísí rẹ̀ kò dára,ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.
3. Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.
4. Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
5. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.