24. Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára,tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan?
25. OLUWA ní:“Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára,tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan.N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà,n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là.
26. N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ:wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí,gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé,èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ,Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.”