Aisaya 47:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Inú bí mi sí àwọn eniyan mi,mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra.Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,o kò ṣàánú wọn.O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn.

7. O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae,nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn,o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn.

8. “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,tí o jókòó láìléwu,tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,‘Èmi nìkan ni mo wà,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.N kò ní di opó,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’

9. Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì,lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó,ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́,kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ.

10. “Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ,o ní ẹnìkan kò rí ọ.Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà,ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà.Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

11. Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró;àjálù yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀;ìparun yóo dé bá ọ lójijì,tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

Aisaya 47