Aisaya 47:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni.Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba,ìwọ ọmọbinrin Kalidea.A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́.

2. Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà,ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò,ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀,kí o sì la odò kọjá.

3. A óo tú ọ sí ìhòòhò,a óo sì rí ìtìjú rẹ.N óo gbẹ̀san,n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí.

4. Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

5. OLUWA wí nípa Kalidea pé:“Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ,ìwọ ọmọbinrin Kalidea.Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́.

Aisaya 47