Aisaya 41:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.

11. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ runni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,wọn óo sì ṣègbé.

12. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,o kò ní rí wọn.Àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóo di òfo patapata.

13. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,èmi ni mo sọ fún ọ pékí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”

14. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,ẹ̀yin ọmọ Israẹli,OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.

15. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,tí ó mú, tí ó sì ní eyín,ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.

16. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWAẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.

17. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.

18. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi.

19. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.

20. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”

21. OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.

22. Ẹ mú wọn wá,kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;kí á lè mọ àyọrísí wọn,tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”

Aisaya 41