Aisaya 41:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù,kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn,kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn,ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́.

2. “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.

3. A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.

4. Ta ló ṣe èyí?Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.

5. “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.

Aisaya 41