Aisaya 40:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye,ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́,tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀,tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án?

15. Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi,ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n.Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè.

16. Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun.

17. Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀,wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n.

18. Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe;tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bòtí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún?

20. Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ,a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà.

21. Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?Ẹ kò sì tíì gbọ́?Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:

22. Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.

23. Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,ó sọ àwọn olóyè ayé di asán.

Aisaya 40