Aisaya 39:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.”

4. Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.”

5. Aisaya bá sọ fún Hesekaya, pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun wí:

6. Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

7. ‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ”

8. Hesekaya dá Aisaya lóhùn, ó ní, “Ohun rere ni OLUWA sọ.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó rò pé alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo wà ní àkókò tòun.

Aisaya 39