Aisaya 38:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”

2. Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA,

3. ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4. OLUWA bá sọ fún Aisaya pé

5. kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀.

6. OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó.

7. Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:

8. Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.

9. Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:

10. Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.

11. Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,ati pé n kò ní sí láàyè mọ́láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.

12. A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.

Aisaya 38