Aisaya 35:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn,aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná.

2. Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó,yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin.Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni.Wọn óo rí ògo OLUWA,wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa.

3. Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró.Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun.

4. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé:“Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù.Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san,ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun;ó ń bọ̀ wá gbà yín là.”

Aisaya 35