Aisaya 33:23-24 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.

24. Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé,“Ara mi kò yá.”A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.

Aisaya 33