12. Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,ẹ sì gbára lé wọn,
13. nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.
14. Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀,tí ó fọ́ yángá-yángá,tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀,tí a lè fi fọn iná ninu ààrò,tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.”
15. Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀,ẹ óo rí ìgbàlà;bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,ẹ óo lágbára.Ṣugbọn ẹ kọ̀.
16. Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni.Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ.Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn.Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín,wọn óo lè sáré gan-an ni.
17. Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan,gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-untítí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè.Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.”
18. Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín,ó ti ṣetán láti ṣàánú yín.Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́.Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA.
19. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.
20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.
21. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”
22. Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”
23. OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀.